news

Followers

DARAPỌ̀ PẸ̀LÚ ÌFẸ̀HÓNÚHÀN ALÁGBÁRA TI ỌJỌ́ KEJÌLÁ OṢÙ KẸFÀ LÁTI FI ÒPIN SÍ ÌJỌBA BURÚKÚ, Ẹ JẸ KÍ Á GBA Ẹ̀MÍ LÀ!

THE YORUBA EDITION OF:

JOIN THE JUNE 12 MASS ACTION TO KICK OFF AN END TO BAD GOVERNMENT, LET'S SAVE LIVES!



Kì í ṣe ohun tuntun mọ́ pé àwọn ènìyàn orílẹ̀-èdè Nàìjíríà tí wà lábẹ́ adarí burúkú, àìní-ìtọ́ni lórí ètò àwùjọ àti ètò òṣèlú, àti ètò ọrọ̀ ajé tí àsárà ti dé bá látàrí ìwà olè, ìmúnisìn, ìnilára àti àsìlò agbára láti ọwọ́ àwọn aláìbìkítà ẹgbẹ́ PDD/APC to tí kọjá àti èyí tó ń ṣe ìjọba lọ́wọ́. 


Ó ṣeni láàánú pé orílẹ̀-èdè tí wọ́n ti sọ àsọtẹ́lẹ̀ pé yóò di alágbára ńlá káàkiri àgbáyé ni ọdún 2020 ti rí ìyọnu láti ọwọ́ àwọn ọ̀kánjúà, aláìmọ̀kan, aláìkójú-òṣùwọ̀n àti atúrọ́tà ènìyàn tí a pè ní adarí tí wọ́n sì ń gba ipò láàrín ara wọn láti ọdún 1960 wá. Ó sì ń yani lẹ́nu pé orílẹ̀-èdè tó ti ń pèsè epo rọ̀bì fún ọgọ́ta ọdún ó lé láìyẹsẹ̀ ní wọ́n dé ní adé gẹ́gẹ́ bí orílẹ̀-èdè tí ìṣẹ́ ti gbilẹ̀ jùlọ lágbàáyé. Ní ọdún 2020, Nàìjíríà ń tá ìwọ̀n àgbá epo mílíọ̀nù méjì lójúmọ́ kan, síbẹ̀ ó jẹ́ ohun ìnira fún àwọn ọmọ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà láti jẹun ní ẹ̀ẹ̀mẹta lójúmọ́.


Ní àsìkò ìbújáde àjàkálẹ̀ àrùn corvid 19 ní ọdún 2020, ìṣénimọ́lé kànńpá tí wọn kò ti bìkítà fún mẹ̀kúnnù tí ó wáyé nígbà náà fi àwọn ọmọ orílẹ̀ èdè yìí sínú ìnira ńlá látàrí àwọn okòwò tó ń forí sánpọ́n, tí ọ̀pọ̀ àwọn ènìyàn sì ń gbé ìgbé ayé olòsì. Èyí tí ó tilẹ̀ wá ba gbogbo ọ̀rọ̀ jẹ́ ni ti ètò ìlera tó mẹ́hẹ àti àwọn òṣìṣẹ́ eléètò ìlera tí wọn fi ebi pa; wọn sì kọ̀ láti fún wọn ní owó àjẹ́mọ́nú, irinṣẹ́ to bágbàmu ni ti ètò ìlera láti lè kojú ooru àjàkálẹ̀ àrùn tí ó múlẹ̀ náà. Orílẹ̀-èdè wa ọ̀wọ́n gbé gbogbo ara lé ìrànlọ́wọ́ láti ilẹ̀ òkèèrè láti mú kí ẹ̀ka ìlera rẹ̀ ṣe ojúṣe wọn nítorí kò sí ohun kankan tó ṣe é tọ́ka sí ní ẹ̀ka náà. Wọ́n kúkú ti kó gbogbo ọrọ̀ wá mì yán-án yán-án. 


Àjọ International Monetary Fund (IMF) fi mílíọ̀nù mẹ́ta àti ogún ọ̀kẹ́ dọ́là ṣe ìrànwọ́ fún ìjọba orílẹ̀-èdè Nàìjíríà láti gbógun ti àrùn covid 19, kí wọ́n sì pèsè paliétíìfù fún àwọn ènìyàn láti mú ìdẹ̀rùn bá wọn nínú ọ̀rọ̀ ajé tó gbẹ́nu sókè látàrí ìbújáde àrùn Covid-19. Síbẹ̀, kò sí ìdàgbàsókè kan gbòógì ní ẹ̀ka ìlera. Owó kékeré ni wọ́n ń san fún àwọn òṣìṣẹ́ elétò ìlera tí wọ́n kò sì yé jẹ wọ́n ní owó oṣù ní ọ̀pọ̀ ìgbà. Láti fi kún ìwà ọ̀dáju ìjọba burúkú yìí, ṣe ni wọ́n tún kó gbogbo àwọn paliétíìfù oúnjẹ tí àwọn ilé-iṣẹ́ ńlá ńlá lábẹ́lé kó fún wọn láti pín fún àwọn ènìyàn pamọ́. Ìgbà mìíràn wà tí àwọn adarí wa burúkú yìí jí àwọn oúnjẹ wọ̀nyí. Àjẹbánu ni àwọn adarí ìjọba ni ìpele ìjọba ìbílẹ̀, ìjọba ìpínlẹ̀ àti ìjọba àpapọ̀ kó owó ìjọba jẹ débi pé àwọn Ìpínlẹ̀ kan kò lè san owó oṣù àwọn òṣìṣẹ́ wọ́n bí ó ti tọ́ mọ́. Àìríṣẹ́ṣe tí di ìdá mẹ́tàlélọ́gbọ̀n nínú ọgọ́rùn-ún, láàrin gbogbo ìwọ̀nyí, àwọn ìkà olórí wá wọ̀nyí sì ń fi kún iye owó epo, èyí tí wọ́n sún láti náírà márùndínláàádọ́ta fún lítà kan sí náírà mẹ́tàdínláàádọ́sàn-án ní báyìí àwọn gómìnà Ìpínlẹ̀ ti fẹnu kò sí ẹ̀kúnwó ọ̀rìnlélọ́ọ̀ọ́dúnrún naira. Fún ìdí èyí, ọ̀wọ́ngógó ti fẹnu sọ ètò ọrọ̀ ajé wá ní ọ̀gangan ẹ̀mí, ojoojumọ́ sì ni náírà ń di pọ̀ọ́ǹtọ̀ síi lẹ́gbẹ dọ́là. 

Iye tí wọn ń ta àwọn oúnjẹ, àti àwọn nǹkan mìíràn lọ́jà ti gbẹ́nu sókè, bẹ́ẹ̀ ni owo ọkọ káàkiri gan án gbẹnu tán, nígbà tí owó ọ̀yà tó kéré jù tí ìjọba ń fún àwọn òṣìṣẹ́ kò ní agbára láti gbọ́ bùkátà wọn. Fún ìdí èyí, àwọn òṣìṣẹ́ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà lábẹ́ owó ọ̀yà tó kéré yìí, èyí tí ó jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn owó ọ̀yà òṣìṣẹ́ tó kéré jù lọ lágbàáyé kò lè bọ́ ẹbí wọn débi pé yóò gbọ́ ètò ìlera tó dára. Wọn kò lè rán àwọn ọmọ wọn ní àwọn ilé-ẹ̀kọ́ gíga tí wọ́n pè ní ti ìjọba. Ní ohun tí ó sì jẹ́ pé àwọn olóṣèlú máa ń rán àwọn ọmọ wọn lọ kẹ́kọ̀ọ́ nílùú òkèèrè bí wọ́n ṣe máa ń rin ìrìn àjò láti tọ́jú ara wọn. Wọ́n tún máa ń san owó oṣù àti àjẹmọ́nú gọbọi fún ara wọn, èyí tí ó jẹ́ pé yóò gbà òṣìṣẹ́ tí ó ń gba owó ọ̀yà ẹgbẹ̀rún lọ́nà ọgbọ́n náírà lọ́wọ́ ìjọba ní ó lé ní ọdún mọ́kànlélọ́gọ́ta láti rí owó oṣù kan dondo ti gómìnà ń gbà ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà. 


Àìsí-ààbò náà kún ìṣòro yìí, èyí tó mú kí ìdigunjalè, ìjínigbé, àti àwọn ìwà ìkà mìíràn ti di ọ̀nà ìpawówọlé nítorí ọ̀pọ̀ àwọn ọ̀dọ́ ń là kàkà láti rí iṣẹ́ aláyéere tí yóò máa pèsè fún wọn. Fún ìdí èyí, àìsí ètò ààbò tí jẹ ilẹ̀ wa ku eegun èyí tí ó ti sọ ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn di aláìnílé ní orílẹ̀-èdè wọn. Àwọn àgbẹ̀ kò lè lọ sí oko pẹ̀lú ìfọ̀kànbalẹ̀, àwọn ọmọ ilé-ẹ̀kọ́ kò lè lọ sí ilé-ẹ̀kọ́ bẹ́ẹ̀ ni àwọn onímọ́tò kò lè rìnnà nítorí ìbẹ̀rù ìjínigbé, ìpàniyàn, ìfipábánilòpọ̀, abbl. 


Ní ọ̀pọ̀ ìgbà ni àwọn ọ̀daràn máa ń gbádùn ààbò láti ọwọ́ ìjọba, èyí sì máa ń fún wọn ní àǹfààní láti dá ọ̀ràn sí i. Ìjọba Ọ̀gágun Muhammadu Buhari lábẹ́ ẹgbẹ́ òṣèlú APC fi ààyè gba àwọn ọ̀daràn, ó sì dà bí ẹni pé ìjọba náà jẹ́ ibi ìsádi fún àwọn alátìlẹ́yìn ìwà ìgbésùnmọ̀mí àti ìwà ọ̀daràn. Èyí ṣàlàyé ìdí tí ìjọba náà ṣe kùnà nínú ohun tí ó yẹ́ kò jẹ́ ohun tí ó ṣe pàtàkì jùlọ fún ìjọba yòówù nítorí ẹ̀mí ènìyàn kò níye lórí mọ́ ni orílẹ̀-èdè Nàìjíríà..


Ìjọba orílẹ̀-èdè Nàìjíríà ti dì ògbóǹtarìgì nínú 'ṣíṣe ìjọba ẹlẹ́yàmẹ̀yà' nípa títú irọ́ tà, lílo ète àti àwọn ọgbọ́n ẹ̀tàn mìíràn láti dá ọ̀tẹ̀ sílẹ̀ kí wọ́n sì pín àwọn ènìyàn orílẹ̀-èdè yìí láti yàgò fún ìsọ̀kan. Wọ́n gbé àwọn onírúurú ọ̀nà kalẹ̀ láti sí ojú wa kúrò lára ìwà olè àti ìwà ìkà wọn gbogbo, wọn sì fi ọ̀gbọọgbọ́n pín wa sí ẹ̀yàmẹ́yà nípasẹ̀ òṣèlú, ẹ̀yà àti ẹ̀sìn wá. 


Àsìkò ti tó fún àwọn ènìyàn rere ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà láti dìde ní ìsọ̀kan, ohùn kan àti agbára; kí wọ́n sì gba orílẹ̀-èdè yìí kúrò lọ́wọ́ àwọn ọ̀jẹ̀lú, àwọn ìsọ̀rí ènìyàn kan náà tí wọ́n kàn ń pààrọ̀ orúkọ ẹgbẹ́ (APC/PDP) nígbà tí wọ́n bá ti mọ̀ pé èrè ń bẹ níbẹ̀. Ó ṣe pàtàkì fún wa láti mọ ìṣòro wa kí á lè mọ ọ̀nà àbáyọ tí ó dára jù. Ìṣòro wà gan an ni àwọn ọ̀tá ìtẹ̀síwájú orílẹ̀-èdè yìí tí wọ́n wà ní ipò ìjọba láti ìjọba àpapọ̀ dé ìgbèríko. Ọ̀nà àbáyọ ni kí á kórajọpọ̀ ní ìsọ̀kan láti mú òpin bá àrékérekè wọn, kí á sì pinnu ìpín àti ètò òṣèlú orílẹ̀-èdè wa fún ọjọ́ iwájú. 


A kò ní jẹ́ kí enikeni kó wa láyà jẹ tàbí kí wọ́n fi ẹ̀tàn tí kò tó nǹkan kọ ẹ̀yìn wá síra nítorí a mọ̀ pé ìṣòro wa kì í ṣe ẹ̀yà Haúsá, Fúlàní, Ìgbò tàbí Yorùbá, bẹ́ẹ̀ ni kì í ṣe àwọn Mùsùlùmí tàbí Kìrìsìtẹ́nì. Àwọn tí ó di ipò ìjọba mú tí wọ́n ti jẹ̀ àná, òní àti ọjọ́ iwájú èmi àti ìwọ. Lára wọn ni a sì ti rí Haúsá, Fúlàní, Ìgbò, Yorùbá, lára wọn náà ni àwọn Mùsùlùmí àti Kìrìsìtẹ́nì wà abbl. 


Ọ̀nà kan ṣoṣo láti gba òmìnira tòótọ́ ni láti fi òpin sí ìjọba wọn, kí a bẹ̀rẹ̀ ìgbé ayé tuntun àti àwùjọ fún ara wa àti àwọn ìran tó ń bọ̀. ÀSÌKÒ TI TÓ!


Àwọn ohun tí a fẹ́ nìyí:


*Ẹ̀dínkù sí owó oṣù àwọn olóṣèlú* Sísan owó oṣù tó ṣe é gbé ayé fún àwọn òṣìṣẹ́ * Ṣíṣí àwọn ẹnu ibodè wa gbogbo láti kó ohun jíjẹ wọlé * Ìdájọ́ òdodo fún àwọn tó fara káásá rògbòdìyàn ENDSARS * Fífi òpin sí ìwé òfin ọdún 1999 * Fífi òpin sí ọ̀ràn dídá àti Ìgbésùnmọ̀mí * Ìdásílẹ̀ àwọn ajàjàǹgbara gbogbo tí wọ́n tì mọ́lé * Dídá owó iná padà sí bí ó ti wà tẹ́lẹ̀* Fífi òpin sí ìyanṣẹ́lódì àjọ ASUP* Ìdápadà owó epo bẹntiróòlù sí iye tí ó ti wà tẹ́lẹ̀ rí kí á sì yéé fowó kún un mọ́* Ṣíṣe ìdápadà àwọn ẹgbẹ́ òṣèlú tí wọ́n yọ orúkọ wọn kúrò gẹ́gẹ́ bí ẹgbẹ́ tó ti forúkọ sílẹ̀ * Pantami gbọ́dọ̀ lọ rọ́kún nílé* Buhari gbọ́dọ̀ fi ipò sílẹ̀ 


#REVOLUTIONNOW #BUHARIMUSTGO #JUNE12PROTEST

1 comment

Poster Speaks

Poster Speaks/box

Trending

randomposts